Matthew 9:1-8

Jesu mú arọ láradá

1 aJesu bọ́ sínú ọkọ̀, ó sì rékọjá odò lọ sí ìlú abínibí rẹ̀ 2 bÀwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí àkéte rẹ̀. Nígbà tí Jesu rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

3Nígbà yìí ni àwọn olùkọ́ òfin wí fún ara wọn pé, “Ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀-òdì!”

4Jesu sì mọ̀ èrò inú wọn, ó wí pé, “Nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń ro búburú nínú yín? 5Èwo ni ó rọrùn jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ;’ tàbí wí pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn?’ 6Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.” 7Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀. 8Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn.

Copyright information for YorBMYO